Nípa Chronicity Care Africa (About Chronicity Care Africa)
Àye ayélujára ‘Chronicity Care Africa’ jẹ́ onírúurú èdè orí ẹ̀rọ̣ ayélujára, ibùdó onírúurú ìbára ẹ̣ni sọ̀rọ̀ tí n pèsè ìmọ̀ràn tí ó wúlò lóde òní lóri bí a ṣ̣e le ṣ̣e ìdìwọ́ àti ìṣàkóso àwọn àìsàn àìlópin tí ó lè jẹ̣́ oníbàjẹ́ gẹ̣́gẹ̣́bi àtọ̀gbẹ, ẹ̀jẹ̀ ríru àti àruǹ tó jọ mọ ìdińkù ímọ̀ àti ìgbàgbé.
Ìdí tí a se dá ‘Chronicity Care Africa’ sílẹ̀ (Purpose of Chronicity Care Africa)
Títi ọ̣̣dún 2030, àwọn àrùn oníbàjé bíi ààrun jẹjẹrẹ, àruǹ tó jọ mọ ìdińkù ímọ̀ àti ìgbàgbé, àtọ̀gbẹ, ati ẹ̀jẹ̀ ríru máa jẹ́ àruǹ tí óńfa ọ̣̀pọ̣̀lọ̣pọ̣̀ ikú ní orílẹ̀-èdè Áfíríkà. Ńitórínàà, óse pàtàkì wípé àwọ̣n agbègbè Áfíríkà àti ìgbèríko rẹ̀ mó bí àwọn àrùn wọ̀nyí ṣ̣e tàn káàkiri tó, kí a sì kọ̣ ẹkọ́ bí a ṣe lè ṣe ìdíwọ́ àti ìṣàkóso wọn dáradára.
Láti ṣ̣à àṣ̣eyọ̣́rí yí, aó nílò àwọn ìpolongo ìlera gbogbogbò tí ó bá agbègbè tí ó tọ́ mu àti èyítí ó ṣe àkíyèsí àwọn ìhùwàsí àṣ̣à àti àwọn àyidàyídà àwùjọ.
Àwọn ọ̀nà wa (Our Methods)
Lílo àwọn ìrírí ti àwọn agbègbè ti ó ní àìsàn Oníbàjẹ́ àti àwọn ìmọ̀ràn ìwádìí àti ẹ̣̀rí ètò ìmúlò ti àwọn iwáàdí ọ̀mọ̀wé, ìpolongo ìlera gbogbogbò yóò fi ìmọ̀ràn tí ó dá lóri ẹ̀rí haǹ ní pa búlọ́ọ́gì, àgbéléra, ìfihàn àwòrán, fáìlì ohùn àfetígbọ́ oní nọ́mbà (tí ó wà lórí ińtánẹ́ẹtì fuń gbígbà láti ayélujára sí kọ̀ǹpútà tàbí ẹ̀rọ aláàgbéká), àwọn èré ẹ̀fẹ̀ àti àwọn ìdánilárayá. Àwọn ònkàwé yóò ní ànfàní sí àwọn orísun wọ̀nyí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èdè bi Akan, Yorùbá ati Pídgìn.
Ojú òpó wẹ́ẹ́bù yìí jẹ́ apákan isẹ́ ìwáàdí ‘Chronicity and Care in African Contexts’ lábẹẹ ákoso Ọ̀jọ̀gbọ́n Ama de-Graft Aikins (UCL Institute of Advanced Studies) tí agbátẹrù rẹ̀ jẹ́ British Academy.